Yorùbá Bibeli

Esr 2:48-64 Yorùbá Bibeli (YCE)

48. Awọn ọmọ Resini, awọn ọmọ Nekoda, awọn ọmọ Gassamu,

49. Awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Pasea, awọn ọmọ Besai,

50. Awọn ọmọ Asna, awọn ọmọ Mehunimi, awọn ọmọ Nefusimi,

51. Awọn ọmọ Bakbuki, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Har-huri,

52. Awọn ọmọ Basluti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harṣa,

53. Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama,

54. Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa,

55. Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Peruda,

56. Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli,

57. Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Ami.

58. Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni, jẹ irinwo o din mẹjọ.

59. Awọn wọnyi li o si goke wá lati Telmela, Telkarsa, Kerubu, Addani, ati Immeri: ṣugbọn nwọn kò le fi idile baba wọn hàn, ati iru ọmọ wọn, bi ti inu Israeli ni nwọn iṣe:

60. Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ãdọtalelẹgbẹta o le meji.

61. Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Hakosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o fẹ ọkan ninu awọn ọmọ Barsillai obinrin, ara Gileadi li aya, a si pè e nipa orukọ wọn;

62. Awọn wọnyi li o wá iwe itan wọn ninu awọn ti a ṣiro nipa itan idile, ṣugbọn a kò ri wọn, nitori na li a ṣe yọ wọn kuro ninu oye alufa.

63. Balẹ si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o má jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi dide pẹlu Urimu ati pẹlu Tummimu.

64. Apapọ gbogbo ijọ na, jẹ ẹgbã mọkanlelogun o le ojidinirinwo.