Yorùbá Bibeli

Esr 2:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI li awọn ọmọ igberiko Juda ti o goke wa, lati inu igbèkun awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnessari, ọba Babiloni, ti ko lọ si Babiloni, ti nwọn si pada wá si Jerusalemu ati Juda, olukuluku si ilu rẹ̀:

2. Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin ninu awọn enia Israeli:

3. Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbọkanla o din mejidilọgbọn.

4. Awọn ọmọ Ṣefatiah, irinwo o din mejidilọgbọn.