Yorùbá Bibeli

Esr 10:16-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ṣugbọn awọn ọmọ igbekun ṣe bẹ̃. Ati Esra, alufa, pẹlu awọn olori ninu awọn baba, nipa ile baba wọn, ati gbogbo wọn nipa orukọ wọn li a yà si ọ̀tọ, ti nwọn si joko li ọjọ kini oṣu kẹwa, lati wadi ọ̀ran na.

17. Nwọn si ba gbogbo awọn ọkunrin ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe ṣe aṣepari, li ọjọ ekini oṣu ekini.

18. Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa, a ri awọn ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe: ninu awọn ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati awọn arakunrin rẹ̀; Maaseiah, ati Elieseri, ati Jaribi ati Gedaliah.

19. Nwọn si fi ọwọ wọn fun mi pe: awọn o kọ̀ awọn obinrin wọn silẹ; nwọn si fi àgbo kan rubọ ẹ̀ṣẹ nitori ẹbi wọn.

20. Ati ninu awọn ọmọ Immeri; Hanani ati Sebadiah.

21. Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Maaseiah, ati Elija, ati Ṣemaiah, ati Jehieli, ati Ussiah.

22. Ati ninu awọn ọmọ Paṣuri; Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Nataneeli Josabadi, ati Eleasa.

23. Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Josabadi, ati Ṣimei, ati Kelaiah (eyi ni Kelita) Petahiah, Juda, ati Elieseri.

24. Ninu awọn akọrin pẹlu; Eliaṣibu: ati ninu awọn adèna; Ṣallumu, ati Telemi, ati Uri.

25. Pẹlupẹlu ninu Israeli: ninu awọn ọmọ Paroṣi: Ramiah, ati Jesiah, ati Malkiah, ati Miamini, ati Eleasari, ati Malkijah, ati Benaiah.

26. Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Mattaniah, Sekariah, ati Jehieli, ati Abdi, ati Jeremoti, ati Elijah.

27. Ati ninu awọn ọmọ Sattu; Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, ati Jeremoti, ati Sabadi, ati Asisa.