Yorùbá Bibeli

Esr 1:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun ekini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ OLUWA lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, OLUWA rú ẹmi Kirusi, ọba Persia soke, ti o mu ki a kede yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, a si kọwe rẹ̀ pẹlu wipe,

2. Bayi ni Kirusi ọba Persia wi pe, OLUWA, Ọlọrun ọrun, ti fi gbogbo ijọba aiye fun mi; o si ti pa a li aṣẹ lati kọ ile fun on ni Jerusalemu ti o wà ni Juda.

3. Tani ninu nyin ninu gbogbo enia rẹ̀? ki Ọlọrun rẹ̀ ki o wà pẹlu rẹ̀, ki o si goke lọ si Jerusalemu, ti o wà ni Juda, ki o si kọ ile OLUWA Ọlọrun Israeli, on li Ọlọrun, ti o wà ni Jerusalemu.

4. Ati ẹnikẹni ti o kù lati ibikibi ti o ti ngbe, ki awọn enia ibugbe rẹ̀ ki o fi fadaka ràn a lọwọ, pẹlu wura, ati pẹlu ẹrù, ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, pẹlu ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu.

5. Nigbana ni awọn olori awọn baba Juda ati Benjamini dide, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu gbogbo awọn ẹniti Ọlọrun rú ẹmi wọn soke, lati goke lọ, lati kọ́ ile OLUWA ti o wà ni Jerusalemu.

6. Gbogbo awọn ti o wà li agbegbe wọn si fi ohun-èlo fadaka ràn wọn lọwọ, pẹlu wura, pẹlu ẹrù ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, ati pẹlu ohun iyebiye, li aika gbogbo ọrẹ atinuwa.