21. Ati awọn ọmọ Ishari; Kora, ati Nefegi, ati Sikri.
22. Ati awọn ọmọ Ussieli; Miṣaeli, ati Elsafani, ati Sitri.
23. Aaroni si fẹ́ Eliṣeba, ọmọbinrin Aminadabu, arabinrin Naṣoni, li aya; on si bí Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari fun u.
24. Ati awọn ọmọ Kora; Assiri, ati Elkana, ati Abiasafu; wọnyi ni idile awọn ọmọ Kora.
25. Eleasari ọmọ Aaroni si fẹ́ ọkan ninu awọn ọmọbinrin Putieli li aya; on si bi Finehasi fun u: wọnyi li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi ni idile wọn.
26. Wọnyi ni Aaroni on Mose na, ẹniti OLUWA sọ fun pe, Ẹ mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.
27. Awọn wọnyi li o bá Farao ọba Egipti sọ̀rọ lati mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni Egipti: wọnyi ni Mose ati Aaroni na.
28. O si ṣe li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ ni ilẹ Egipti,
29. Ni OLUWA sọ fun Mose wipe, Emi li OLUWA: sọ gbogbo eyiti mo wi fun ọ fun Farao ọba Egipti.
30. Mose si wi niwaju OLUWA pe, Kiyesi i, alaikọlà ète li emi, Farao yio ha ti ṣe fetisi ti emi?