Yorùbá Bibeli

Eks 39:10-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nwọn si tò ẹsẹ̀ okuta mẹrin si i: ẹsẹ̀ ekini ni sardiu, ati topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini.

11. Ati ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi.

12. Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu.

13. Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, oniki, ati jasperi: a si tò wọn si oju-ìde wurà ni titò wọn.

14. Okuta wọnni si jasi gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn, bi ifin èdidi-àmi, olukuluku ti on ti orukọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ya mejejila.

15. Nwọn si ṣe ẹ̀wọn iṣẹ-ọnà-lilọ kìki wurà si igbàiya na.

16. Nwọn si ṣe oju-ìde wurà meji, ati oruka wurà meji; nwọn si fi oruka mejeji si eti igbàiya na mejeji.

17. Nwọn si fi ẹ̀wọn wurà iṣẹ-ọnà-lilọ mejeji bọ̀ inu oruka wọnni, ni eti igbàiya na.

18. Ati eti mejeji ti ẹ̀wọn iṣẹ-lilọ mejeji nì ni nwọn fi mọ́ inu oju-ìde mejeji, nwọn si fi wọn sara okùn ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀.

19. Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si eti mejeji igbàiya na, si eti rẹ̀ ti o wà, ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inu.

20. Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si ìha mejeji ẹ̀wu-efodi na nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ki o kọjusi isolù rẹ̀, loke ọjá ẹ̀wu-efodi na.

21. Nwọn si fi oruka rẹ̀ dè igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi pẹlu ọjá-àwọn aṣọ-aláró, ki o le ma wà lori onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ati ki igbàiya ni ki o máṣe tú kuro lara ẹ̀wu-efodi na; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

22. O si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni iṣẹ wiwun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ-aláró.

23. Oju-ọrùn si wà li agbedemeji aṣọ-igunwa na, o dabi oju-ẹ̀wu ogun, pẹlu ọjá yi oju na ká, ki o máṣe ya.

24. Nwọn si ṣe pomegranate aṣọ: alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ si iṣẹti aṣọ-igunwa na.

25. Nwọn si ṣe ṣaworo kìki wurà, nwọn si fi ṣaworo na si alafo pomegranate wọnni si eti iṣẹti aṣọ igunwa na, yiká li alafo pomegranate wọnni;

26. Ṣaworo kan ati pomegranate kan, ṣaworo kan ati pomegranate kan, yi iṣẹti aṣọ-igunwa na ká lati ma fi ṣiṣẹ alufa; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

27. Nwọn si ṣe ẹ̀wu ọ̀gbọ daradara ti iṣẹ híhun fun Aaroni, ati fun awọn ọmo rẹ̀,

28. Ati fila ọṣọ́ ọ̀gbọ daradara, ati fila ọ̀gbọ didara, ati ṣòkoto ọ̀gbọ olokún wiwẹ,