Yorùbá Bibeli

Eks 39:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NWỌN si fi ninu aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, dá aṣọ ìsin, lati ma fi sìn ni ibi mimọ́, nwọn si dá aṣọ mimọ́ ti iṣe fun Aaroni; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

2. O si ṣe ẹ̀wu-efodi na ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.

3. Nwọn si lù wurà nì di ewé fẹlẹfẹlẹ, nwọn si là a li okùn wẹ́wẹ, ati lati fi ṣe iṣẹ ọlọnà sinu aṣọ-alaró, ati sinu elesè-àluko, ati sinu ododó, ati sinu ọ̀gbọ didara nì.

4. Nwọn ṣe aṣọ ejika si i, lati so o lù: li eti mejeji li a so o lù.

5. Ati onirũru-ọnà ọjá ti o wà lara rẹ̀, lati fi dì i o jẹ́ ọkanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, aṣọ-alaró, elesè-àluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

6. Nwọn si ṣiṣẹ́ okuta oniki ti a tò sinu oju-ìde wurà, ti a fin bi ifin èdidi-àmi ti a fin orukọ awọn ọmọ Israeli si.

7. O si fi wọn si ejika ẹ̀wu-efodi na, li okuta, iranti fun awọn ọmọ Israeli: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

8. O si fi iṣẹ ọlọnà ṣiṣẹ igbàiya na, bi iṣẹ ẹ̀wu-efodi nì; ti wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododo, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.

9. Oniha mẹrin ọgbọgba ni; nwọn ṣe igbàiya na ni iṣẹpo meji: ika kan ni gigùn rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀, o jẹ́ iṣẹpo meji.

10. Nwọn si tò ẹsẹ̀ okuta mẹrin si i: ẹsẹ̀ ekini ni sardiu, ati topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini.

11. Ati ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi.

12. Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu.

13. Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, oniki, ati jasperi: a si tò wọn si oju-ìde wurà ni titò wọn.