Yorùbá Bibeli

Eks 38:23-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ati Oholiabu pẹlu rẹ̀, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, alagbẹdẹ, ati ọlọgbọ́n ọlọnà, alaró ati ahunṣọ alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara.

24. Gbogbo wurà ti a lò si iṣẹ na, ni onirũru iṣẹ ibi mimọ́ nì, ani wurà ọrẹ nì, o jẹ́ talenti mọkandilọgbọ̀n, ati ẹgbẹrin ṣekeli o din ãdọrin, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́.

25. Ati fadakà awọn ẹniti a kà ninu ijọ-enia jẹ́ ọgọrun talenti, ati ṣekeli ojidilẹgbẹsan o le mẹdogun, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́:

26. Abọ ṣekeli kan li ori ọkunrin kọkan, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́, lori ori olukuluku ti o kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ le ẹgbẹtadilogun o le ãdọjọ enia.

27. Ati ninu ọgọrun talenti fadakà na li a ti dà ihò-ìtẹbọ wọnni ti ibi mimọ́, ati ihò-ìtẹbọ ti aṣọ-ikele na, ọgọrun ihò-ìtẹbọ ninu ọgọrun talenti na, talenti ka fun ihò-ìtẹbọ kan.

28. Ati ninu ojidilẹgbẹsan ṣekeli o le mẹdogun, o mú ṣe kọkọrọ fun ọwọ̀n wọnni, o si fi i bò ori wọn, o si fi i ṣe ọjá wọn.

29. Ati idẹ ọrẹ na jẹ́ ãdọrin talenti, ati egbejila ṣekeli.

30. On li o si fi ṣe ihò-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ati pẹpẹ idẹ na, ati àro idẹ sara rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na,

31. Ati ihò-ìtẹbọ agbalá, na yikà, ati ìho-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agbalá, ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati gbogbo ekàn agbalà na yikà.