Yorùbá Bibeli

Eks 28:38-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

38. On o si ma wà niwaju ori Aaroni, ki Aaroni le ma rù ẹ̀ṣẹ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yio si yàsimimọ́, ninu gbogbo ẹ̀bun mimọ́ wọn: on o si ma wà niwaju ori rẹ̀ nigbagbogbo, ki OLUWA ki o le ni inudidùn si wọn.

39. Iwọ o si fi ọ̀gbọ didara wun ẹ̀wu-awọtẹlẹ, iwọ o si fi ọ̀gbọ didara ṣe fila, iwọ o si fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe ọjá-amure.

40. Iwọ o si dá ẹ̀wu-awọtẹlẹ fun awọn ọmọ Aaroni, iwọ o si dá ọjá-amure fun wọn, iwọ o si dá fila fun wọn, fun ogo ati fun ọṣọ́.

41. Iwọ o si fi wọn wọ̀ Aaroni arakunrin rẹ, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; iwọ o si ta oróro si wọn li ori, iwọ o si yà wọn simimọ́, iwọ o si sọ wọn di mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

42. Iwọ o si dá ṣòkoto ọ̀gbọ fun wọn lati ma fi bò ìhoho wọn, ki o ti ibadi dé itan:

43. Nwọn o si wà lara Aaroni, ati lara awọn ọmọ rẹ̀, nigbati nwọn ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ, lati ṣiṣẹ ni ibi mimọ́; ki nwọn ki o má ba dẹ̀ṣẹ, nwọn a si kú: ìlana lailai ni fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.