Yorùbá Bibeli

Eks 26:11-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ idẹ, ki o si fi ikọ́ wọnni sinu ojóbo, ki o si fi so agọ́ na pọ̀, yio si jẹ́ ọkan.

12. Ati iyokù ti o kù ninu aṣọ-tita agọ́ na, àbọ aṣọ-tita ti o kù, yio rọ̀ sori ẹhin agọ na.

13. Ati igbọnwọ kan li apa kan, ati igbọnwọ kan li apa keji, eyiti o kù ni ìna aṣọ-tita agọ́ na, yio si rọ̀ si ìha agọ́ na ni ìha ihin ati ni ìha ọhún, lati bò o.

14. Iwọ o si ṣe ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa fun agọ́ na, ati ibori awọ seali lori rẹ̀.

15. Iwọ o si ṣe apáko igi ṣittimu fun agọ́ na li ogurodo.

16. Igbọnwọ mẹwa ni gigùn apáko na, ati igbọnwọ kan on àbọ ni ibò apáko kan.

17. Ìtẹbọ meji ni ki o wà li apáko kan, ti o tò li ẹsẹ-ẹsẹ̀ si ara wọn: bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo apáko agọ́ na.

18. Iwọ o si ṣe apáko agọ́ na, ogún apáko ni ìha gusù si ìha gusù.

19. Iwọ o si ṣe ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà nisalẹ ogún apáko wọnni; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan fun ìtẹbọ meji na, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji fun ìtẹbọ meji na;

20. Ati ìha keji agọ́ na ni ìha ariwa, ogún apáko ni yio wà nibẹ̀:

21. Ati ogoji ihò-ìtẹbọ fadakà wọn; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko na kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji.

22. Ati fun ìha agọ́ na ni ìha ìwọ-õrùn apáko mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe.

23. Ati apáko meji ni iwọ o ṣe fun igun agọ́ na ni ìha ẹhin rẹ̀.

24. A o si so wọn pọ̀ nisalẹ, a o si so wọn pọ̀ li oke ori rẹ̀ si oruka kan: bẹ̃ni yio si ṣe ti awọn mejeji; nwọn o si ṣe ti igun mejeji.

25. Nwọn o si jẹ́ apáko mẹjọ, ati ihò-ìtẹbọ fadakà wọn, ihò-ìtẹbọ mẹrindilogun; ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko kan, ati ihò-ìtẹbọ meji nisalẹ apáko keji.

26. Iwọ o si ṣe ọpá idabu igi ṣittimu; marun fun apáko ìha kan agọ́ na,

27. Ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha keji agọ́ na, ati ọpá idabu marun fun apáko na ni ìha agọ́ na, fun ìha mejeji ni ìha ìwọ-õrùn.