Yorùbá Bibeli

Eks 25:25-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Iwọ o si ṣe eti kan bi ibú-atẹlẹwọ si i yiká, iwọ o si ṣe igbáti wurà si eti rẹ̀ yiká.

26. Iwọ o si ṣe oruka wurà mẹrin si i, iwọ o si fi oruka wọnni si igun mẹrẹrin, ti o wà li ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹrin.

27. Li abẹ igbáti na li oruka wọnni yio wà, fun ibi ọpá lati ma fi rù tabili na.

28. Iwọ o si ṣe ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi wurà bò wọn, ki a le ma fi wọn rù tabili na.

29. Iwọ o si ṣe awopọkọ rẹ̀, ati ṣibi rẹ̀, ati ìgo rẹ̀, ati awo rẹ̀, lati ma fi dà: kìki wurà ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn.

30. Iwọ o si ma gbé àkara ifihàn kalẹ lori tabili na niwaju mi nigbagbogbo.

31. Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́:

32. Ẹka mẹfa ni yio yọ ni ìha rẹ̀; ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha kan, ati ẹka mẹta ọpá-fitila na ni ìha keji:

33. Ago mẹta ni ki a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi ati itanna li ẹka kan; ati ago mẹta ti a ṣe bi itanna almondi li ẹka ekeji, pẹlu irudi ati itanna: bẹ̃li ẹka mẹfẹ̃fa ti o yọ lara ọpá-fitila na.

34. Ati ninu ọpá-fitila na li ago mẹrin yio wà ti a ṣe bi itanna almondi, pẹlu irudi wọn ati itanna wọn.

35. Irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, irudi kan yio si wà nisalẹ ẹka rẹ̀ meji ki o ri bakanna, gẹgẹ bi ẹka rẹ̀ mẹfẹfa ti o ti ara ọpá-fitila na yọ jade.

36. Irudi wọn ati ẹka wọn ki o ri bakanna: ki gbogbo rẹ̀ ki o jẹ́ lilù kìki wurà kan.

37. Iwọ o si ṣe fitila rẹ̀ na, meje: ki nwọn ki o si fi fitila wọnni sori rẹ̀, ki nwọn ki o le ma ṣe imọlẹ si iwaju rẹ̀.

38. Ati alumagaji rẹ̀, ati awo alumagaji rẹ̀, kìki wurà ni ki o jẹ́.