Yorùbá Bibeli

Eks 23:25-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Ẹnyin o si ma sìn OLUWA Ọlọrun nyin, on o si busi onjẹ rẹ, ati omi rẹ; emi o si mú àrun kuro lãrin rẹ.

26. Obinrin kan ki yio ṣẹ́nu, bẹ̃ni ki yio yàgan ni ilẹ rẹ: iye ọjọ́ rẹ li emi ó fi kún.

27. Emi o rán ẹ̀ru mi siwaju rẹ, emi o si dà gbogbo awọn enia rú ọdọ ẹniti iwọ o dé, emi o si mu gbogbo awọn ọtá rẹ yi ẹ̀hin wọn dà si ọ.

28. Emi o si rán agbọ́n siwaju rẹ, ti yio lé awọn enia Hifi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn enia Hitti kuro niwaju rẹ.

29. Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju rẹ li ọdún kan; ki ilẹ na ki o má ba di ijù, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba rẹ̀ si ọ.

30. Diẹdiẹ li emi o ma lé wọn jade kuro niwaju rẹ, titi iwọ o fi di pupọ̀, ti iwọ o si tẹ̀ ilẹ na dó.

31. Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yio fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ̀ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ.

32. Iwọ kò gbọdọ bá wọn ṣe adehùn, ati awọn oriṣa wọn pẹlu.

33. Nwọn kò gbọdọ joko ni ilẹ rẹ, ki nwọn ki o má ba mu ọ ṣẹ̀ si mi: nitori bi iwọ ba sìn oriṣa wọn, yio ṣe idẹkùn fun ọ nitõtọ.