Yorùbá Bibeli

Eks 19:23-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Mose si wi fun OLUWA pe, Awọn enia ki yio le wá sori oke Sinai: nitoriti iwọ ti kìlọ fun wa pe, Sọ agbàra yi oke na ká, ki o si yà a si mimọ́.

24. OLUWA si wi fun u pe, Lọ, sọkalẹ; ki iwọ ki o si goke wá, iwọ ati Aaroni pẹlu rẹ: ṣugbọn ki awọn alufa ati awọn enia ki o máṣe yà lati goke tọ̀ OLUWA wá, ki o má ba kọlù wọn.

25. Bẹ̃ni Mose sọkalẹ tọ̀ awọn enia lọ, o si sọ̀rọ fun wọn.