Yorùbá Bibeli

Eks 17:3-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ongbẹ omi si ngbẹ awọn enia na nibẹ̀; awọn enia na si nkùn si Mose, nwọn si wipe, Ẽtiri ti iwọ fi mú wa goke lati Egipti wá, lati fi ongbẹ pa wa ati awọn ọmọ wa, ati ẹran wa?

4. Mose si kepè OLUWA, wipe, Kili emi o ṣe fun awọn enia yi? nwọn fẹrẹ̀ sọ mi li okuta.

5. OLUWA si wi fun Mose pe, Kọja lọ siwaju awọn enia na, ki o si mú ninu awọn àgbagba Israeli pẹlu rẹ, ki o si mú ọpá rẹ, ti o fi lù odò nì li ọwọ́ rẹ, ki o si ma lọ.

6. Kiyesi i, emi o duro niwaju rẹ nibẹ̀ lori okuta ni Horebu; iwọ o si lù okuta na, omi yio si jade ninu rẹ̀, ki awọn enia ki o le mu. Mose si ṣe bẹ̃ li oju awọn àgbagba Israeli.

7. O si sọ orukọ ibẹ̀ ni Massa, ati Meriba, nitori asọ̀ awọn ọmọ Israeli, ati nitoriti nwọn dan OLUWA wò pe, OLUWA ha mbẹ lãrin wa, tabi kò si?

8. Nigbana li Amaleki wá, o si bá Israeli jà ni Refidimu.