Yorùbá Bibeli

Eks 12:47-51 Yorùbá Bibeli (YCE)

47. Gbogbo ijọ Israeli ni yio ṣe e.

48. Nigbati alejò kan ba nṣe atipo lọdọ rẹ, ti o si nṣe ajọ irekọja si OLUWA, ki a kọ gbogbo ọkunrin rẹ̀ nilà, nigbana ni ki ẹ jẹ ki o sunmọtosi, ki o si ṣe e; on o si dabi ẹniti a bi ni ilẹ na: nitoriti kò si ẹni alaikọlà ti yio jẹ ninu rẹ̀.

49. Ofin kan ni fun ibilẹ ati fun alejò ti o ṣe atipo ninu nyin.

50. Bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ Israeli ṣe; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe.

51. O si ṣe li ọjọ́ na gan, OLUWA mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.