Yorùbá Bibeli

Eks 10:14-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Awọn eṣú na si goke sori ilẹ Egipti gbogbo, nwọn si bà si ẹkùn Egipti gbogbo; nwọn papọ̀ju, kò si irú eṣú bẹ̃ ṣaju wọn, bẹ̃ni lẹhin wọn irú wọn ki yio si si.

15. Nitoriti nwọn bò oju ilẹ gbogbo, tobẹ̃ ti ilẹ fi ṣú; nwọn si jẹ gbogbo eweko ilẹ na, ati gbogbo eso igi ti yinyin kù silẹ: kò si kù ohun tutù kan lara igi, tabi lara eweko igbẹ́, já gbogbo ilẹ Egipti.

16. Nigbana ni Farao ranṣẹ pè Mose ati Aaroni kánkan; o si wipe, Emi ti ṣẹ̀ si OLUWA Ọlọrun nyin, ati si nyin.

17. Njẹ nitorina emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ẹ̀ṣẹ mi jì lẹ̃kanṣoṣo yi, ki ẹ si bẹ̀ OLUWA Ọlọrun nyin, ki o le mú ikú yi kuro lọdọ mi.

18. On si jade kuro niwaju Farao, o si bẹ̀ OLUWA.

19. OLUWA si yi afẹfẹ ìwọ-õrùn lile-lile ti o si fẹ́ awọn eṣú na kuro, o si gbá wọn lọ sinu Okun Pupa; kò si kù eṣú kanṣoṣo ni gbogbo ẹkùn Egipti.

20. Ṣugbọn OLUWA mu àiya Farao le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ.

21. OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si ọrun, ki òkunkun ki o ṣú yiká ilẹ Egipti, ani òkunkun ti a le fọwọbà.

22. Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si ọrun; òkunkun biribiri si ṣú ni gbogbo ilẹ Egipti ni ijọ́ mẹta:

23. Nwọn kò ri ara wọn, bẹ̃li ẹnikan kò si dide ni ipò tirẹ̀ ni ijọ́ mẹta: ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Israeli li o ni imọle ni ibugbé wọn.

24. Farao si pè Mose, o si wipe, Ẹ ma lọ, ẹ sìn OLUWA; kìki agbo ati ọwọ́-ẹran nyin ni ki o kù lẹhin; ki awọn ewe nyin ki o bá nyin lọ pẹlu.

25. Mose si wipe, Iwọ kò le ṣaima fun wa li ohun ẹbọ pẹlu ati ẹbọ sisun, ti awa o fi rubọ si OLUWA Ọlọrun wa.