Yorùbá Bibeli

Ẹk. Jer 5:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Awọn baba wa ti ṣẹ̀, nwọn kò si sí; awa si nrù aiṣedede wọn.

8. Awọn ẹrú ti jọba lori wa: ẹnikan kò si gbà wa kuro li ọwọ wọn.

9. Ninu ewu ẹmi wa li awa nlọ mu onjẹ wa, nitori idà ti aginju.

10. Àwọ wa pọ́n gẹgẹ bi àro nitori gbigbona ìyan na.

11. Nwọn tẹ́ awọn obinrin li ogo ni Sioni, awọn wundia ni ilu Juda.

12. A so awọn ijoye rọ̀ nipa ọwọ wọn: a kò buyin fun oju awọn àgbagba.

13. Awọn ọdọmọkunrin ru ọlọ, ãrẹ̀ mu awọn ọmọde labẹ ẹrù-igi.

14. Awọn àgbagba dasẹ kuro li ẹnu-bode, awọn ọdọmọkunrin kuro ninu orin wọn.