Yorùbá Bibeli

Ẹk. Jer 5:10-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Àwọ wa pọ́n gẹgẹ bi àro nitori gbigbona ìyan na.

11. Nwọn tẹ́ awọn obinrin li ogo ni Sioni, awọn wundia ni ilu Juda.

12. A so awọn ijoye rọ̀ nipa ọwọ wọn: a kò buyin fun oju awọn àgbagba.

13. Awọn ọdọmọkunrin ru ọlọ, ãrẹ̀ mu awọn ọmọde labẹ ẹrù-igi.

14. Awọn àgbagba dasẹ kuro li ẹnu-bode, awọn ọdọmọkunrin kuro ninu orin wọn.

15. Ayọ̀ ọkàn wa ti dá; a yi ijo wa pada si ọ̀fọ.

16. Ade ṣubu kuro li ori wa: ègbe ni fun wa, nitori awa ti ṣẹ̀.

17. Nitori eyi li ọkàn wa rẹ̀wẹsi; nitori nkan wọnyi oju wa di baibai.

18. Nitori oke Sioni, ti dahoro, awọn kọ̀lọkọlọ nrin lori rẹ̀.

19. Iwọ, Oluwa, li o wà lailai; itẹ́ rẹ lati iran de iran!

20. Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe wa lailai, ti o si kọ̀ wa silẹ li ọjọ pipẹ?

21. Oluwa, yi wa pada sọdọ rẹ, awa o si yipada; sọ ọjọ wa di ọtun gẹgẹ bi ti igbãni.

22. Tabi iwọ ha ti kọ̀ wa silẹ patapata, tobẹ̃ ti iwọ si binu si wa gidigidi?