Yorùbá Bibeli

Ẹk. Jer 5:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. RANTI, Oluwa, ohun ti o de sori wa; rò ki o si wò ẹ̀gan wa!

2. A fi ogún wa le awọn alejo lọwọ, ile wa fun awọn ajeji.

3. Awa jẹ alaini obi, baba kò si, awọn iyá wa dabi opó.

4. Awa ti fi owo mu omi wa; a nta igi wa fun wa.

5. Awọn ti nlepa wa sunmọ ọrùn wa: ãrẹ̀ mu wa, awa kò si ni isimi.

6. Awa ti fi ọwọ wa fun awọn ara Egipti, ati fun ara Assiria, lati fi onjẹ tẹ́ wa lọrùn.

7. Awọn baba wa ti ṣẹ̀, nwọn kò si sí; awa si nrù aiṣedede wọn.

8. Awọn ẹrú ti jọba lori wa: ẹnikan kò si gbà wa kuro li ọwọ wọn.