Yorùbá Bibeli

Amo 9:11-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Li ọjọ na li emi o gbe agọ Dafidi ti o ṣubu ró, emi o si dí ẹya rẹ̀; emi o si gbe ahoro rẹ̀ soke, emi o si kọ́ ọ bi ti ọjọ igbani:

12. Ki nwọn le ni iyokù Edomu ni iní, ati ti gbogbo awọn keferi, ti a pè nipa orukọ mi, li Oluwa ti o nṣe eyi wi.

13. Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkorè bá, ati ẹniti o ntẹ̀ eso àjara yio le ẹniti o nfunrùgbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ́.

14. Emi o si tun mu igbèkun Israeli enia mi padà bọ̀, nwọn o si kọ́ ahoro ilu wọnni, nwọn o si ma gbe inu wọn; nwọn o si gbin ọgbà-àjara, nwọn o si mu ọti-waini wọn; nwọn o ṣe ọgbà pẹlu, nwọn o si jẹ eso inu wọn.

15. Emi o si gbìn wọn si ori ilẹ wọn, a kì yio si fà wọn tu mọ kuro ninu ilẹ wọn, ti mo ti fi fun wọn, li Oluwa Ọlọrun rẹ wi.