Yorùbá Bibeli

Amo 6:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitorina awọn ni o lọ si igbèkun pẹlu awọn ti o ti kọ́ lọ si igbèkun; àse awọn ti nṣe aṣeleke li a o mu kuro.

8. Oluwa Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ bura, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ ogun wi, Emi korira ọlanla Jakobu, mo si korira ãfin rẹ̀: nitorina li emi o ṣe fi ilu na, ati ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀ tọrẹ.

9. Yio si ṣe, bi enia mẹwa li o ba kù ninu ile kan, nwọn o si kú.

10. Ati arakunrin rẹ̀, ati ẹniti o nfi i joná, lati kó egungun wọnni jade kuro ninu ile, yio gbe e, yio si bi ẹniti o wà li ẹba ile lere pe, O ha tun kù ẹnikan pẹlu rẹ? On o si wipe, Bẹ̃kọ̀. Nigbana li on o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ: nitoripe awa kò gbọdọ da orukọ Oluwa.

11. Nitori kiyesi i, Oluwa paṣẹ, yio si fi iparun kọlù ile nla na, ati aisàn kọlù ile kékèké.

12. Ẹṣin ha le ma sure lori apata? ẹnikan ha le fi akọ malu ṣiṣẹ ìtulẹ̀ nibẹ̀? nitoriti ẹnyin ti yi idajọ dà si oró, ati eso ododo dà si iwọ:

13. Ẹnyin ti nyọ̀ si ohun asan, ti nwipe, Nipa agbara ara wa kọ́ li awa fi gbà iwo fun ara wa?

14. Ṣugbọn kiyesi i, emi o gbe orilẹ-ède kan dide si nyin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi; nwọn o si pọ́n nyin loju lati iwọle Hamati, titi de odò pẹ̀tẹlẹ.