Yorùbá Bibeli

Amo 6:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EGBE ni fun ẹniti ara rọ̀ ni Sioni, ati awọn ti o gbẹkẹ̀le oke nla Samaria, awọn ti a pè ni ikini ninu awọn orilẹ-ède, awọn ti ile Israeli tọ̀ wá!

2. Ẹ kọja si Kalne, si wò; ẹ si ti ibẹ̀ lọ si Hamati nla: lẹhìn na ẹ sọ̀kalẹ lọ si Gati ti awọn Filistini: nwọn ha san jù ilẹ ọba wọnyi lọ? tabi agbègbe wọn ha tobi jù agbègbe nyin lọ?

3. Ẹnyin ti o sún ọjọ ibi siwaju, ti ẹ si mu ibùgbe ìwa-ipá sunmọ tòsi;

4. Awọn ti o ndùbulẹ lori akete ehin-erin, ti nwọn si nnà ara wọn lori irọ̀gbọku wọn, ti nwọn njẹ ọdọ-agùtan inu agbo, ati ẹgbọ̀rọ malu inu agbo;

5. Ti nwáhùn si iró orin fioli, ti nwọn si nṣe ohun-ikọrin fun ara wọn, bi Dafidi;

6. Awọn ti nmuti ninu ọpọ́n waini, ti nwọn si nfi olori ororo kun ara wọn; ṣugbọn nwọn kò banujẹ nitori ipọnju Josefu.

7. Nitorina awọn ni o lọ si igbèkun pẹlu awọn ti o ti kọ́ lọ si igbèkun; àse awọn ti nṣe aṣeleke li a o mu kuro.

8. Oluwa Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ bura, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ ogun wi, Emi korira ọlanla Jakobu, mo si korira ãfin rẹ̀: nitorina li emi o ṣe fi ilu na, ati ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀ tọrẹ.

9. Yio si ṣe, bi enia mẹwa li o ba kù ninu ile kan, nwọn o si kú.