Yorùbá Bibeli

Amo 5:2-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Wundia Israeli ti ṣubu; kì yio dide mọ: a kọ̀ ọ silẹ lori ilẹ rẹ̀; kò si ẹniti yio gbe e dide.

3. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ilu ti o jade lọ li ẹgbẹrun yio ṣikù ọgọrun; eyiti o si jade lọ li ọgọrun yio ṣikù mẹwa, fun ile Israeli.

4. Nitori bayi li Oluwa wi fun ile Israeli, ẹ wá mi, ẹnyin o si yè:

5. Ṣugbọn ẹ máṣe wá Beteli, bẹ̃ni ki ẹ má wọ̀ inu Gilgali lọ, ẹ má si rekọja lọ si Beerṣeba: nitori lõtọ Gilgali yio lọ si igbèkun, Beteli yio si di asan.

6. Ẹ wá Oluwa, ẹnyin o si yè; ki o má ba gbilẹ bi iná ni ile Josefu, a si jó o run, ti kì o fi si ẹnikan lati pá a ni Beteli.

7. Ẹnyin ti ẹ sọ idajọ di iwọ, ti ẹ si kọ̀ ododo silẹ li aiye.

8. Ẹ wá ẹniti o dá irawọ̀ meje nì ati Orioni, ti o si sọ ojiji ikú di owurọ̀, ti o si fi oru mu ọjọ ṣokùnkun: ti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade soju aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀:

9. Ti o mu iparun kọ manà sori alagbara, tobẹ̃ ti iparun yio wá si odi agbara.

10. Nwọn korira ẹniti nbaniwi li ẹnu bodè, nwọn si korira ẹniti nsọ otitọ.

11. Nitorina niwọ̀n bi itẹ̀mọlẹ nyin ti wà lori talakà, ti ẹnyin si gba ẹrù alikama lọwọ rẹ̀: ẹnyin ti fi okuta ti a gbẹ́ kọ́ ile, ṣugbọn ẹ kì o gbe inu wọn; ẹnyin ti gbìn ọgbà àjara daradara, ṣugbọn ẹ kì o mu ọti-waini wọn.