Yorùbá Bibeli

Amo 5:13-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitorina ẹni-oye yio dakẹ nigbana; nitori akòko ibi ni.

14. Ẹ ma wá ire, kì isi iṣe ibi, ki ẹ ba le yè; bẹ̃ni Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, yio si pẹlu nyin, bi ẹnyin ti wi.

15. Ẹ korira ibi, ẹ si fẹ́ ire, ki ẹ si fi idajọ gunlẹ ni bodè; boya Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun yio ṣe ojurere si iyokù Josefu.

16. Nitorina Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ani Oluwa wi bayi pe, Ẹkun yio wà ni gbogbo ita; nwọn o si ma wi ni gbogbo òpopó ọ̀na pe, Ã! ã! nwọn o si pè agbẹ̀ si iṣọ̀fọ, ati iru awọn ti o gbọ́n lati pohùnrére si isọkún.

17. Ati ni gbogbo ọ̀gba àjara ni isọkún yio gbe wà: nitori emi o kọja lãrin rẹ, li Oluwa wi.

18. Egbe ni fun ẹnyin ti ẹ nfẹ́ ọjọ Oluwa! kili eyi o jasi fun nyin? ọjọ Oluwa òkunkun ni, kì isi iṣe imọlẹ.

19. Gẹgẹ bi enia ti o sa fun kiniun, ti beari si pade rẹ̀; tabi ti o wọ̀ inu ile, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ tì lara ogiri, ti ejò si bù u jẹ.

20. Ọjọ Oluwa kì o ha ṣe òkunkun laiṣe imọlẹ? ani òkunkun biribiri, laisi imọlẹ ninu rẹ̀?

21. Mo korira, mo si kẹgàn ọjọ asè nyin, emi kì o si gbõrùn ọjọ ajọ ọ̀wọ nyin.

22. Bi ẹnyin tilẹ rú ẹbọ sisun ati ẹbọ jijẹ nyin si mi, emi kì o si gbà wọn: bẹ̃ni emi ki yio nani ẹbọ ọpẹ́ ẹran abọ́pa nyin.

23. Mu ariwo orin rẹ kuro lọdọ mi; nitori emi kì o gbọ́ iró adùn fioli rẹ.

24. Ṣugbọn jẹ ki idajọ ki o ṣàn silẹ bi omi, ati ododo bi iṣàn omi nla.

25. Ẹnyin ha ti rubọ si mi, ẹ ha ti ta mi lọrẹ li aginjù li ogoji ọdun, ẹnyin ile Israeli.

26. Ṣugbọn ẹnyin ti rù agọ Moloku ati Kiuni nyin, awọn ere nyin, irawọ̀ òriṣa nyin, ti ẹ ṣe fun ara nyin.