Yorùbá Bibeli

Amo 5:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ yi ti emi gbe soke si nyin, ani ohùnrére ẹkun, ẹnyin ile Israeli.

2. Wundia Israeli ti ṣubu; kì yio dide mọ: a kọ̀ ọ silẹ lori ilẹ rẹ̀; kò si ẹniti yio gbe e dide.

3. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ilu ti o jade lọ li ẹgbẹrun yio ṣikù ọgọrun; eyiti o si jade lọ li ọgọrun yio ṣikù mẹwa, fun ile Israeli.

4. Nitori bayi li Oluwa wi fun ile Israeli, ẹ wá mi, ẹnyin o si yè:

5. Ṣugbọn ẹ máṣe wá Beteli, bẹ̃ni ki ẹ má wọ̀ inu Gilgali lọ, ẹ má si rekọja lọ si Beerṣeba: nitori lõtọ Gilgali yio lọ si igbèkun, Beteli yio si di asan.

6. Ẹ wá Oluwa, ẹnyin o si yè; ki o má ba gbilẹ bi iná ni ile Josefu, a si jó o run, ti kì o fi si ẹnikan lati pá a ni Beteli.

7. Ẹnyin ti ẹ sọ idajọ di iwọ, ti ẹ si kọ̀ ododo silẹ li aiye.

8. Ẹ wá ẹniti o dá irawọ̀ meje nì ati Orioni, ti o si sọ ojiji ikú di owurọ̀, ti o si fi oru mu ọjọ ṣokùnkun: ti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade soju aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀:

9. Ti o mu iparun kọ manà sori alagbara, tobẹ̃ ti iparun yio wá si odi agbara.