Yorùbá Bibeli

Amo 2:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ṣugbọn mo pa ará Amori run niwaju wọn, giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati egbò rẹ̀ lati isalẹ wá.

10. Emi mu nyin goke pẹlu lati ilẹ Egipti wá, mo si sìn nyin li ogoji ọdun là aginjù ja, lati ni ilẹ awọn Amori.

11. Mo si gbe ninu ọmọkunrin nyin dide lati jẹ woli, ati ninu awọn ọdọmọkunrin nyin lati jẹ Nasarite. Bẹ̃ ki o ri, ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi.

12. Ṣugbọn ẹnyin fun awọn Nasarite ni ọti-waini mu, ẹ si paṣẹ fun awọn woli pe, Ẹ máṣe sọtẹlẹ.

13. Wò o, emi o tẹ̀ nyin mọlẹ, bi kẹkẹ́ ti o kún fun ití ti itẹ̀.

14. Nitorina sisá yio dẹti fun ẹni yiyara, onipá kì yio si mu ipa rẹ̀ le, bẹ̃ni alagbara kì yio le gba ara rẹ̀ là.

15. Bẹ̃ni tafàtafà kì yio duro; ati ẹniti o yasẹ̀ kì yio le gbà ara rẹ̀ là: bẹ̃ni ẹniti ngùn ẹṣin kì yio gbà ara rẹ̀ là:

16. Ati ẹniti o gboiyà ninu awọn alagbara yio salọ ni ihòho li ọjọ na, li Oluwa wi.