Nigbana li awọn ọkunrin mararun na lọ, nwọn si dé Laiṣi, nwọn si ri awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, bi nwọn ti joko laibẹ̀ru, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Sidoni, ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru; kò si sí olori kan ni ilẹ na, ti iba mu oju tì wọn li ohunkohun, nwọn si jìna si awọn ara Sidoni, nwọn kò si ba ẹnikẹni ṣe.