LI ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: ati li ọjọ́ wọnni ẹ̀ya Dani nwá ilẹ-iní kan lati joko si; nitoripe titi o fi di ọjọ́ na, ilẹ-iní wọn lãrin awọn ẹ̀ya Israeli kò ti ibọ́ si ọwọ́ wọn.