Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si sọkalẹ lọ si Aṣkeloni, o si pa ọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn, o si kò ẹrù wọn, o si fi ìparọ aṣọ fun awọn ti o já alọ́ na. Ibinu rẹ̀ si rú, on si gòke lọ si ile baba rẹ̀.