12. Ki ile rẹ ki o si dabi ile Peresi, ẹniti Tamari bi fun Juda, nipa irú-ọmọ ti OLUWA yio fun ọ lati ọdọ ọmọbinrin yi.
13. Boasi si mú Rutu, on si di aya rẹ̀; nigbati o si wọle tọ̀ ọ, OLUWA si mu ki o lóyun, o si bi ọmọkunrin kan.
14. Awọn obinrin si wi fun Naomi pe, Olubukun li OLUWA, ti kò fi ọ silẹ li ainí ibatan li oni, ki o si jẹ́ olokikí ni Israeli.
15. On o si jẹ́ olumupada ẹmi rẹ, ati olutọju ogbó rẹ: nitori aya-ọmọ rẹ, ẹniti o fẹ́ ọ, ti o san fun ọ jù ọmọkunrin meje lọ, li o bi i.
16. Naomi si gbé ọmọ na, o si tẹ́ ẹ si owókan-àiya rẹ̀, o si di alagbatọ́ rẹ̀.
17. Awọn obinrin aladugbo rẹ̀ si sọ ọ li orukọ, wipe, A bi ọmọkunrin kan fun Naomi; nwọn si pè orukọ rẹ̀ ni Obedi: on ni baba Jesse, baba Dafidi.
18. Wọnyi ni iran Peresi: Peresi bi Hesroni;
19. Hesroni si bi Ramu, Ramu si bi Amminadabu;
20. Amminadabu si bi Naṣoni, Naṣoni si bi Salmoni;
21. Salmoni si bi Boasi, Boasi si bi Obedi;
22. Obedi si bi Jesse, Jesse si bi Dafidi.