Yorùbá Bibeli

O. Daf 97 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọlọrun Ọba Atóbijù

1. OLUWA jọba; ki aiye ki o yọ̀; jẹ ki inu ọ̀pọlọpọ erekuṣu ki o dùn.

2. Awọsanma ati okunkun yi i ka: ododo ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ̀.

3. Iná ṣaju rẹ̀, o si jo awọn ọta rẹ̀ yika kiri.

4. Manamana rẹ̀ kọ imọlẹ si aiye: aiye ri i, o si wariri.

5. Awọn òke nyọ́ bi ida niwaju Oluwa, niwaju Oluwa gbogbo aiye:

6. Ọrun fi ododo rẹ̀ hàn, gbogbo orilẹ-ède si ri ogo rẹ̀.

7. Oju yio tì gbogbo awọn ti nsìn ere fifin, ẹniti nfi ere ṣe ileri ara wọn: ẹ ma sìn i, gbogbo ẹnyin ọlọrun.

8. Sioni gbọ́, inu rẹ̀ si dùn; awọn ọmọbinrin Juda si yọ̀, Oluwa, nitori idajọ rẹ.

9. Nitoripe Iwọ Oluwa, li o ga jù gbogbo aiye lọ: Iwọ li a gbé ga jù gbogbo oriṣa lọ.

10. Ẹnyin ti o fẹ Oluwa, ẹ korira ibi: o pa ọkàn awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ́: o gbà wọn li ọwọ awọn enia buburu.

11. A funrugbin imọlẹ fun olododo, ati inu didùn fun alaiya diduro.

12. Ẹ yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo; ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀.