Yorùbá Bibeli

O. Daf 82 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọlọrun, Ọba Àwọn Ọba

1. ỌLỌRUN duro ninu ijọ awọn alagbara; o nṣe idajọ ninu awọn ọlọrun.

2. Ẹnyin o ti ṣe idajọ aiṣõtọ pẹ to, ti ẹ o si ma ṣe ojuṣaju awọn enia buburu?

3. Ṣe idajọ talaka, ati ti alaini-baba: ṣe otitọ si awọn olupọnju ati alaini.

4. Gbà talaka ati alaini: yọ wọn li ọwọ awọn enia buburu.

5. Nwọn kò mọ̀, bẹ̃ni nwọn kò fẹ ki oye ki o ye wọn; nwọn nrìn li òkunkun; gbogbo ipilẹ aiye yẹ̀ ni ipò wọn.

6. Emi ti wipe, ọlọrun li ẹnyin; awọn ọmọ Ọga-ogo si ni gbogbo nyin.

7. Ṣugbọn ẹnyin o kú bi enia, ẹnyin o si ṣubu bi ọkan ninu awọn ọmọ-alade.

8. Ọlọrun, dide, ṣe idajọ aiye: nitori iwọ ni yio ni orilẹ-ède gbogbo.