Yorùbá Bibeli

O. Daf 70 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Ìrànlọ́wọ́

1. ỌLỌRUN, yara gbà mi; Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ.

2. Ki oju ki o tì awọn ti nwá ọkàn mi, ki nwọn ki o si dãmu: ki nwọn ki o si pada sẹhin, ki a si dãmu awọn ti nwá ifarapa mi.

3. Ki a pa wọn li ẹhìn dà fun ère itiju awọn ti nwi pe, A! a!

4. Ki gbogbo awọn ti nwá ọ ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn nipa tirẹ: ki iru awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Ki a gbé Ọlọrun ga!

5. Ṣugbọn talaka ati alaini li emi: Ọlọrun, yara si mi: iwọ li oluranlọwọ ati olugbala mi: Oluwa, máṣe pẹ́ titi.