Yorùbá Bibeli

O. Daf 67 Yorùbá Bibeli (YCE)

Orin Ọpẹ́

1. KI Ọlọrun ki o ṣãnu fun wa, ki o si busi i fun wa; ki o si ṣe oju rẹ̀ ki o mọlẹ si wa lara,

2. Ki ọ̀na rẹ ki o le di mimọ̀ li aiye, ati igbala ilera rẹ ni gbogbo orilẹ-ède.

3. Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ.

4. Jẹ ki inu awọn orilẹ-ède ki o dùn, ki nwọn ki o ma kọrin fun ayọ̀: nitoriti iwọ o fi ododo ṣe idajọ enia, iwọ o si jọba awọn orilẹ-ède li aiye.

5. Jẹ ki awọn enia ki o yìn ọ, Ọlọrun; jẹ ki gbogbo enia ki o yìn ọ.

6. Nigbana ni ilẹ yio to ma mu asunkún rẹ̀ wá; Ọlọrun, Ọlọrun wa tikararẹ̀ yio busi i fun wa.

7. Ọlọrun yio busi i fun wa; ati gbogbo opin aiye yio si ma bẹ̀ru rẹ̀.