Yorùbá Bibeli

O. Daf 66 Yorùbá Bibeli (YCE)

Orin Ìyìn ati Ọpẹ́

1. Ẹ hó iho ayọ̀ si Ọlọrun, ẹnyin ilẹ gbogbo:

2. Ẹ kọrin ọlá orukọ rẹ̀: ẹ mu iyìn rẹ̀ li ogo.

3. Ẹ wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti li ẹ̀ru to ninu iṣẹ rẹ! nipa ọ̀pọ agbara rẹ li awọn ọta rẹ yio fi ori wọn balẹ fun ọ.

4. Gbogbo aiye ni yio ma sìn ọ, nwọn o si ma kọrin si ọ; nwọn o ma kọrin si orukọ rẹ.

5. Ẹ wá wò iṣẹ Ọlọrun, o li ẹ̀ru ni iṣe rẹ̀ si awọn ọmọ enia.

6. O sọ okun di ilẹ gbigbẹ: nwọn fi ẹsẹ là odò já: nibẹ li awa gbe yọ̀ ninu rẹ̀.

7. O jọba nipa agbara rẹ̀ lailai; oju rẹ̀ nwò awọn orilẹ-ède: ki awọn ọlọtẹ ki o máṣe gbé ara wọn ga.

8. Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun wa, ẹnyin enia, ki ẹ si mu ni gbọ́ ohùn iyìn rẹ̀.

9. Ẹniti o mu ẹmi wa wà lãye, ti kò si jẹ ki ẹsẹ wa ki o yẹ̀.

10. Ọlọrun, nitori ti iwọ ti ridi wa: iwọ ti dan wa wò, bi ã ti idan fadaka wò.

11. Iwọ mu wa wọ̀ inu àwọn; iwọ fi ipọnju le wa li ẹgbẹ.

12. Iwọ mu awọn enia gùn wa li ori: awa nwọ inu iná ati omi lọ, ṣugbọn iwọ mu wa jade wá si ibi irọra.

13. Emi o lọ sinu ile rẹ ti emi ti ẹbọ sisun: emi o san ẹjẹ́ mi fun ọ,

14. Ti ète mi ti jẹ́, ti ẹnu si ti sọ, nigbati mo wà ninu ipọnju.

15. Emi o ru ẹbọ sisun ọlọra si ọ, pẹlu õrùn ọrá àgbo; emi o rubọ akọ-malu pẹlu ewurẹ.

16. Ẹ wá gbọ́, gbogbo ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, emi o sọ ohun ti o ṣe fun ọkàn mi.

17. Emi fi ẹnu mi kigbe pè e, emi o si fi àhọn mi buyin fun u.

18. Bi emi ba gbà ẹ̀ṣẹ li aiya mi, Oluwa kì yio gbohùn mi:

19. Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun ti gbohùn mi: o si ti fi eti si ohùn adura mi.

20. Olubukún li Ọlọrun, ti kò yi adura mi pada kuro, tabi ãnu rẹ̀ kuro lọdọ mi.