Yorùbá Bibeli

O. Daf 56 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Igbẹkẹ le Ọlọrun

1. ỌLỌRUN, ṣãnu fun mi: nitoriti enia nfẹ gbe mi mì; o mba mi jà lojojumọ, o nni mi lara.

2. Awọn ọta mi nfẹ igbe mi mì lojojumọ: nitori awọn ti nfi igberaga ba mi ja pọ̀.

3. Nigbati ẹ̀ru ba mbà mi, emi o gbẹkẹle ọ.

4. Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀, Ọlọrun li emi o gbẹkẹ mi le, emi kì yio bèru: kili ẹran-ara le ṣe si mi.

5. Lojojumọ ni nwọn nlọ́ ọ̀rọ mi: ibi ni gbogbo ìro inu wọn si mi:

6. Nwọn kó ara wọn jọ, nwọn ba, nwọn kiyesi ìrin mi, nwọn ti nṣọ̀na ọkàn mi.

7. Nwọn ha le ti ipa aiṣedede là? ni ibinu, bi awọn enia na lulẹ̀, Ọlọrun.

8. Iwọ nka ìrìnkiri mi: fi omije mi sinu igo rẹ: nwọn ko ha si ninu iwe rẹ bi?

9. Li ọjọ ti mo ba kigbe, nigbana li awọn ọta mi yio pẹhinda: eyi li emi mọ̀: nitoripe Ọlọrun wà fun mi.

10. Nipa Ọlọrun li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀: nipa Oluwa li emi o ma yìn ọ̀rọ rẹ̀.

11. Ọlọrun li emi gbẹkẹ mi le, emi kì yio bẹ̀ru kili enia le ṣe si mi.

12. Ẹjẹ́ rẹ mbẹ lara mi, Ọlọrun: emi o fi iyìn fun ọ.

13. Nitoripe iwọ li o ti gbà ọkàn mi lọwọ ikú: iwọ ki yio ha gbà ẹsẹ mi lọwọ iṣubu? ki emi ki o le ma rìn niwaju Ọlọrun ni imọlẹ awọn alãye?