Yorùbá Bibeli

O. Daf 54 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Ààbò

1. ỌLỌRUN gbà mi nipa orukọ rẹ, si ṣe idajọ mi nipa agbara rẹ.

2. Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; fi eti si ọ̀rọ ẹnu mi.

3. Nitoriti awọn alejò dide si mi, awọn aninilara si nwá ọkàn mi: nwọn kò kà Ọlọrun si li oju wọn.

4. Kiyesi i, Ọlọrun li oluranlọwọ mi: Oluwa wà pẹlu awọn ti o gbé ọkàn mi duro.

5. Yio si fi ibi san a fun awọn ọta mi: ke wọn kuro ninu otitọ rẹ.

6. Emi o rubọ atinuwa si ọ: Oluwa, emi o yìn orukọ rẹ; nitoriti o dara.

7. Nitori o ti yọ mi kuro ninu iṣẹ́ gbogbo: oju mi si ri ifẹ rẹ̀ lara awọn ọta mi.