Yorùbá Bibeli

O. Daf 3 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Òwúrọ̀ fun Ìrànlọ́wọ́

1. OLUWA, awọn ti nyọ mi li ẹnu ti npọ̀ to yi! ọ̀pọlọpọ li awọn ti o dide si mi.

2. Ọ̀pọlọpọ li awọn ti o nwi niti ọkàn mi pe, Iranlọwọ kò si fun u nipa ti Ọlọrun.

3. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke.

4. Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá.

5. Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin,

6. Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka.

7. Dide Oluwa; gbà mi, Ọlọrun mi: nitori iwọ li o lù gbogbo awọn ọta mi li egungun ẹrẹkẹ; iwọ si ká ehin awọn enia buburu.

8. Ti Oluwa ni igbala: ibukún rẹ si mbẹ lara awọn enia rẹ.