Yorùbá Bibeli

O. Daf 21 Yorùbá Bibeli (YCE)

Orin Ìṣẹ́gun

1. ỌBA yio ma yọ̀ li agbara rẹ, Oluwa; ati ni igbala rẹ, yio ti yọ̀ pọ̀ to!

2. Iwọ ti fi ifẹ ọkàn rẹ̀ fun u, iwọ kò si dù u ni ibère ẹnu rẹ̀.

3. Nitori iwọ ti fi ibukún ore kò o li ọ̀na, iwọ fi ade kiki wura de e li ori.

4. O tọrọ ẹmi lọwọ rẹ, iwọ si fi fun u, ani ọjọ gigùn lai ati lailai.

5. Ogo rẹ̀ pọ̀ ni igbala rẹ: iyìn ati ọlánla ni iwọ fi si i lara.

6. Nitori iwọ ti ṣe e li ẹni-ibukún fun jùlọ titi aiye: iwọ si fi oju rẹ mu u yọ̀ gidigidi.

7. Nitori ti ọba gbẹkẹle Oluwa, ati nipa ãnu Ọga-ogo kì yio ṣipò pada.

8. Ọwọ rẹ yio wá gbogbo awọn ọta rẹ ri: ọwọ ọtún rẹ ni yio wá awọn ti o korira rẹ ri.

9. Iwọ o ṣe wọn bi ileru onina ni igba ibinu rẹ: Oluwa yio gbé wọn mì ni ibinu rẹ̀, iná na yio si jó wọn pa.

10. Eso wọn ni iwọ o run kuro ni ilẹ, ati irú-ọmọ wọn kuro ninu awọn ọmọ enia.

11. Nitori ti nwọn nrò ibi si ọ: nwọn ngbìro ete ìwa-ibi, ti nwọn kì yio le ṣe.

12. Nitorina ni iwọ o ṣe mu wọn pẹhinda, nigbati iwọ ba fi ọfà rẹ kàn ọsán si oju wọn.

13. Ki iwọ ki ó ma leke, Oluwa, li agbara rẹ; bẹ̃li awa o ma kọrin, ti awa o si ma yìn agbara rẹ.