Yorùbá Bibeli

O. Daf 2 Yorùbá Bibeli (YCE)

Àyànfẹ́ Ọlọrun

1. ẼṢE ti awọn orilẹ-ède fi nbinu fùfu, ati ti awọn enia ngbero ohun asan?

2. Awọn ọba aiye kẹsẹ jọ, ati awọn ijoye ngbimọ pọ̀ si Oluwa ati si Ẹni-ororo rẹ̀ pe,

3. Ẹ jẹ ki a fa ìde wọn já, ki a si mu okùn wọn kuro li ọdọ wa.

4. Ẹniti o joko li ọrun yio rẹrin: Oluwa yio yọ ṣùti si wọn.

5. Nigbana ni yio sọ̀rọ si wọn ni ibinu rẹ̀, yio si yọ wọn lẹnu ninu ibinujẹ rẹ̀ kikan.

6. Ṣugbọn mo ti fi Ọba mi jẹ lori Sioni, òke mimọ́ mi.

7. Emi o si rohin ipinnu Oluwa: O ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bi ọ.

8. Bère lọwọ mi, emi o si fi awọn orilẹ-ède fun ọ ni ini rẹ, ati iha opin ilẹ li ọrọ̀-ilẹ rẹ.

9. Ọpá irin ni iwọ o fi fọ́ wọn; iwọ o si rún wọn womuwomu, bi ohun èlo amọ̀.

10. Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n, ẹnyin ọba: ki a si kọ́ nyin, ẹnyin onidajọ aiye.

11. Ẹ fi ìbẹru sìn Oluwa, ẹ si ma yọ̀ ti ẹnyin ti iwarìri.

12. Fi ẹnu kò Ọmọ na lẹnu, ki o máṣe binu, ẹnyin a si ṣegbe li ọ̀na na, bi inu rẹ̀ ba ru diẹ kiun. Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.