Yorùbá Bibeli

O. Daf 149 Yorùbá Bibeli (YCE)

Orin Ìyìn sí OLUWA

1. Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ kọ orin titun si Oluwa, ati iyìn rẹ̀ ninu ijọ awọn enia-mimọ́.

2. Jẹ ki Israeli ki o yọ̀ si ẹniti o dá a; jẹ ki awọn ọmọ Sioni ki o kún fun ayọ̀ si Ọba wọn.

3. Jẹ ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ̀ ninu ijó: jẹ ki nwọn ki o fi ìlu ati dùru kọrin iyìn si i.

4. Nitori ti Oluwa ṣe inudidùn si awọn enia rẹ̀; yio fi igbala ṣe awọn onirẹlẹ li ẹwà.

5. Jẹ ki awọn enia mimọ́ ki o kún fun ayọ̀ ninu ogo; ki nwọn ki o mã kọrin kikan lori ẹni wọn.

6. Ki iyìn Ọlọrun ki o wà li ẹnu wọn, ati idà oloju meji li ọwọ wọn;

7. Lati san ẹsan lara awọn keferi, ati ijiya lara awọn enia.

8. Lati fi ẹ̀wọn dè awọn ọba wọn, ati lati fi ṣẹkẹṣẹkẹ irin dè awọn ọlọ̀tọ wọn;

9. Lati ṣe idajọ wọn, ti a ti kọwe rẹ̀, ọlá yi ni gbogbo enia mimọ́ rẹ̀ ni. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.