1. Ẹ fi iyìn fun Oluwa: nitori ohun rere ni lati ma kọ orin iyìn si Ọlọrun wa: nitori ti o dùn, iyìn si yẹ.
2. Oluwa li o kọ́ Jerusalemu: on li o kó awọn ifọnkalẹ Israeli jọ.
3. O mu awọn onirora aiya lara da: o di ọgbẹ wọn:
4. O ka iye awọn ìrawọ; o si sọ gbogbo wọn li orukọ.
5. Oluwa wa tobi, ati alagbara nla: oye rẹ̀ kò li opin.
6. Oluwa gbé awọn onirẹlẹ soke: o rẹ̀ awọn enia buburu si ilẹyilẹ.
7. Ẹ fi ọpẹ kọrin si Oluwa; kọrin iyìn si Ọlọrun wa lara duru:
8. Ẹniti o fi awọsanma bò oju ọrun, ẹniti o pèse òjo fun ilẹ, ti o mu koriko dàgba lori awọn òke nla.
9. O fi onjẹ ẹranko fun u ati fun ọmọ iwò ti ndún.
10. Kò ṣe inudidùn si agbara ẹṣin: kò ṣe inudidùn si ẹsẹ ọkunrin.