Yorùbá Bibeli

O. Daf 141 Yorùbá Bibeli (YCE)

Adura Ààbò

1. OLUWA, emi kigbe pè ọ: yara si ọdọ mi; fi eti si ohùn mi, nigbati mo ba nkepè ọ.

2. Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ bi ẹbọ turari; ati igbé ọwọ mi soke bi ẹbọ aṣãlẹ.

3. Oluwa, fi ẹṣọ́ siwaju ẹnu mi; pa ilẹkun ète mi mọ́.

4. Máṣe fà aiya mi si ohun ibi kan, lati ma ba awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ ṣiṣẹ buburu; má si jẹ ki emi ki o jẹ ninu ohun didùn wọn.

5. Jẹ ki olododo ki o lù mi; iṣeun ni yio jasi: jẹ ki o si ba mi wi; ororo daradara ni yio jasi, ti kì yio fọ́ mi lori: sibẹ adura mi yio sa wà nitori jamba wọn.

6. Nigbati a ba bì awọn onidajọ wọn ṣubu ni ibi okuta, nwọn o gbọ́ ọ̀rọ mi, nitori ti o dùn.

7. Egungun wa tàn kalẹ li ẹnu isà-òkú, ẹniti o la aporo sori ilẹ.

8. Ṣugbọn oju mi mbẹ lara rẹ; Ọlọrun Oluwa, lọdọ rẹ ni igbẹkẹle mi wà; máṣe tú ọkàn mi dà silẹ.

9. Pa mi mọ́ kuro ninu okùn ti nwọn dẹ silẹ fun mi, ati ikẹkùn awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

10. Jẹ ki awọn enia buburu ki o bọ́ sinu àwọn ara wọn, nigbati emi ba kọja lọ.