1. OLUWA, ranti Dafidi ninu gbogbo ipọnju rẹ̀:
2. Ẹniti o ti bura fun Oluwa, ti o si ṣe ileri ifẹ fun Alagbara Jakobu pe.
3. Nitõtọ, emi kì yio wọ̀ inu agọ ile mi lọ, bẹ̃li emi kì yio gùn ori akete mi;
4. Emi kì yio fi orun fun oju mi, tabi õgbe fun ipenpeju mi,
5. Titi emi o fi ri ibi fun Oluwa, ibujoko fun Alagbara Jakobu.
6. Kiyesi i, awa gburo rẹ̀ ni Efrata: awa ri i ninu oko ẹgàn na.
7. Awa o lọ sinu agọ rẹ̀: awa o ma sìn nibi apoti-itisẹ rẹ̀.
8. Oluwa, dide si ibi isimi rẹ; iwọ, ati apoti agbara rẹ.
9. Ki a fi ododo wọ̀ awọn alufa rẹ: ki awọn enia mimọ rẹ ki o ma hó fun ayọ̀.
10. Nitori ti Dafidi iranṣẹ rẹ, máṣe yi oju ẹni-ororo rẹ pada.
11. Oluwa ti bura nitõtọ fun Dafidi; on kì yio yipada kuro ninu rẹ̀, Ninu iru-ọmọ inu rẹ li emi o gbé kalẹ si ori itẹ́ rẹ.
12. Bi awọn ọmọ rẹ yio ba pa majẹmu mi mọ́ ati ẹri mi ti emi o kọ́ wọn, awọn ọmọ wọn pẹlu yio joko lori itẹ́ rẹ lailai.
13. Nitori ti Oluwa ti yàn Sioni; o ti fẹ ẹ fun ibujoko rẹ̀.
14. Eyi ni ibi isimi mi lailai: nihin li emi o ma gbe; nitori ti mo fẹ ẹ.