Yorùbá Bibeli

O. Daf 129 Yorùbá Bibeli (YCE)

Kí ojú ti ọ̀tá

1. IGBA pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá, ni ki Israeli ki o wi nisisiyi.

2. Igba pupọ̀ ni nwọn ti npọ́n mi loju lati igba-ewe mi wá: sibẹ nwọn kò ti ibori mi.

3. Awọn awalẹ̀ walẹ si ẹhin mi: nwọn si la aporo wọn gigun.

4. Olododo li Oluwa: o ti ke okùn awọn enia buburu kuro.

5. Ki gbogbo awọn ti o korira Sioni ki o dãmu, ki nwọn ki o si yi ẹhin pada.

6. Ki nwọn ki o dabi koriko ori-ile ti o gbẹ danu, ki o to dagba soke:

7. Eyi ti oloko pipa kò kún ọwọ rẹ̀; bẹ̃li ẹniti ndi ití, kò kún apa rẹ̀.

8. Bẹ̃li awọn ti nkọja lọ kò wipe, Ibukún Oluwa ki o pẹlu nyin: awa sure fun nyin li orukọ Oluwa.