Yorùbá Bibeli

O. Daf 128 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìbẹ̀rù OLUWA lérè

1. IBUKÚN ni fun gbogbo ẹniti o bẹ̀ru Oluwa; ti o si nrìn li ọ̀na rẹ̀.

2. Nitori ti iwọ o jẹ iṣẹ́ ọwọ rẹ: ibukún ni fun ọ: yio si dara fun ọ.

3. Obinrin rẹ yio dabi àjara rere eleso pupọ li arin ile rẹ: awọn ọmọ rẹ yio dabi igi olifi yi tabili rẹ ka.

4. Kiyesi i, pe bẹ̃li a o busi i fun ọkunrin na, ti o bẹ̀ru Oluwa.

5. Ki Oluwa ki o busi i fun ọ lati Sioni wá, ki iwọ ki o si ma ri ire Jerusalemu li ọjọ aiye rẹ gbogbo.

6. Bẹ̃ni ki iwọ ki o si ma ri ati ọmọ-de-ọmọ rẹ: ati alafia lara Israeli.