Yorùbá Bibeli

O. Daf 126 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ẹkún Di Ayọ̀

1. NIGBATI Oluwa mu ikólọ Sioni pada, awa dabi ẹniti nla alá.

2. Nigbana li ẹnu wa kún fun ẹrin, ati ahọn wa kọ orin: nigbana ni nwọn wi ninu awọn keferi pe, Oluwa ṣe ohun nla fun wọn.

3. Oluwa ṣe ohun nla fun wa: nitorina awa nyọ̀.

4. Oluwa mu ikólọ wa pada, bi iṣan-omi ni gusu.

5. Awọn ti nfi omije fún irugbin yio fi ayọ ka.

6. Ẹniti nfi ẹkun rìn lọ, ti o si gbé irugbin lọwọ, lõtọ, yio fi ayọ̀ pada wá, yio si rù iti rẹ̀.