Yorùbá Bibeli

O. Daf 11 Yorùbá Bibeli (YCE)

OLUWA ni Igbẹkẹle Àwọn Olódodo

1. OLUWA ni mo gbẹkẹ mi le: ẹ ha ti ṣe wi fun ọkàn mi pe, sá bi ẹiyẹ lọ si òke nyin?

2. Sa kiyesi i, awọn enia buburu ti fà ọrun wọn le, nwọn ti fi ọfa sùn li oju ọṣán, ki nwọn ki o le ta a li òkunkun si ọlọkàn diduro.

3. Bi ipilẹ ba bajẹ, kili olododo yio ṣe?

4. Oluwa mbẹ ninu tempili mimọ́ rẹ̀, itẹ́ Oluwa mbẹ li ọrun: oju rẹ̀ nwò, ipenpeju rẹ̀ ndán awọn ọmọ enia wò.

5. Oluwa ndán olododo wò: ṣugbọn enia buburu ati ẹniti nfẹ ìwa-agbara, ọkàn rẹ̀ korira.

6. Lori enia buburu ni yio rọjo, ẹyín gbigbona ati imi-ọjọ ati iji gbigbona: eyi ni ipin ago wọn.

7. Nitori olododo li Oluwa, o fẹ ododo; awọn ẹniti o duro-ṣinṣin yio ri oju rẹ̀.