2. O si yà ẹnu rẹ̀, o si kọ́ wọn, wipe,
3. Alabukún-fun li awọn òtoṣi li ẹmí: nitori tiwọn ni ijọba ọrun.
4. Alabukún-fun li awọn ẹniti nkãnu: nitoriti a ó tù wọn ninu.
5. Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye.
6. Alabukún-fun li awọn ẹniti ebi npa ati ti ongbẹ ngbẹ sipa ododo: nitori nwọn ó yo.
7. Alabukún-fun li awọn alãnu: nitori nwọn ó ri ãnu gbà.
8. Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun.
9. Alabukún-fun li awọn onilaja: nitori ọmọ Ọlọrun ni a ó ma pè wọn.
10. Alabukúnfun li awọn ẹniti a ṣe inunibini si nitori ododo: nitori tiwọn ni ijọba ọrun.
11. Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọ̀rọ buburu gbogbo si nyin nitori emi.
12. Ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ̀: nitori ère nyin pọ̀ li ọrun: bẹ̃ni nwọn sá ṣe inunibini si awọn wolĩ ti o ti mbẹ ṣaju nyin.