23. Nitorina ni ijọba ọrun fi dabi ọba kan ti nfẹ gbà ìṣirò lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀.
24. Nigbati o bẹ̀rẹ si gbà iṣiro, a mu ọkan tọ̀ ọ wá, ti o jẹ ẹ li ẹgbãrun talenti.
25. Njẹ bi ko ti ni ohun ti yio fi san a, oluwa rẹ̀ paṣẹ pe ki a tà a, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ki a si san gbese na.
26. Nitorina li ọmọ-ọdọ na wolẹ o si tẹriba fun u, o nwipe, Oluwa, mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ.
27. Oluwa ọmọ-ọdọ na si ṣãnu fun u, o tú u silẹ, o fi gbese na jì i.
28. Ṣugbọn nigbati ọmọ-ọdọ na jade lọ, o si ri ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀, ti o jẹ ẹ li ọgọrun owo idẹ: o gbé ọwọ́ le e, o fún u li ọrùn, o wipe, San gbese ti iwọ jẹ mi.
29. Ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀ kunlẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Mu sũru fun mi, emi ó si san gbogbo rẹ̀ fun ọ.
30. On kò si fẹ; o lọ, o gbé e sọ sinu tubu titi yio fi san gbese na.
31. Nigbati awọn iranṣẹ ẹgbẹ rẹ̀ ri eyi ti a ṣe, ãnu ṣe wọn gidigidi, nwọn lọ nwọn si sọ gbogbo ohun ti a ṣe fun oluwa wọn.
32. Nigbati oluwa rẹ̀ pè e tan, o wi fun u pe, A! iwọ iranṣẹ buburu yi, Mo fi gbogbo gbese nì jì ọ, nitoriti iwọ bẹ̀ mi:
33. Iwọ kì isi ṣãnu iranṣẹ ẹgbẹ rẹ gẹgẹ bi mo ti ṣãnu fun ọ?
34. Oluwa rẹ̀ si binu, o fi i fun awọn onitubu, titi yio fi san gbogbo gbese eyi ti o jẹ ẹ.